
Too Much Wahala in This Country
Original Author
Abdulbaseet Yusuff
Translator
Adesiyan Oluwapelumi
Date Published
Too Much Wahala in This Country
(Previously published in Rattle)
Wahala if you are a bystander, watching
the protest from afar; hands tucked in pockets
Wahala if a stray bullet finds a home in
your bones, or your liver
Wahala if you come to lend bass to protest
chants, & hired hoodlums turn it to bedlam
Wahala if you drive there with your Camry
& drive home with a cracked windshield
Wahala if you drive your car through a police
checkpoint at night. Wahala if the road is empty
Wahala if you are the young man behind
the wheels. Wahala if your head isn’t shaven
Wahala if you are nearby when a cop shoots
another cop. Wahala if they wash the blood
off their hands & bath you in it. Wahala if
there is no video evidence to towel you clean
Wahala if you don’t know bigwig lawmakers to
nick you from the jaws of torture
Wahala if police swear they didn’t nab you
Wahala if they actually did nab you & are lying
Wahala if you are already stewing in their belly,
writhing like upset intestines amongst others
in a dingy cell. Wahala if you are unfamiliar with
the smell of conc. piss and shit.
Wahala for your corpse that will never be buried
Wahala for the mother that won’t kiss your cold cheek
Wahala for the river that will eat you
Wahala here, wahala there. Wahala everywhere
But no wahala for the cop whose forefinger twitched
on the trigger like an apoplectic
Wahala for government running out of tricks;
for thinking they can SWAT at us like flies,
Wahala that they do not know their harsh blowings
have stirred wisps of smoke where slumbering
tinder nest once lay. Wahala that they do not
realize they are making dragons out of us
Note: Wahala is Nigerian pidgin for “trouble.”
Wàhálà Púpọ̀ Nínú Orílẹ̀-Èdè Yìí
Wàhálà, bí o bá jẹ́ Olùwòran, tí o ń wo
ìwọ́de láti òkèèrè pẹ̀lú ọwọ́ rẹ wà nínú àpò
Wàhálà, bí ọta ìbọn bá
bálẹ̀ gbá sì nínú egungun rẹ, tàbí ẹ̀dọ̀ rẹ
Wàhálà, bí o bá yá bass fún orin ìwọ́de,
kí àwọn ọmọ ìta sì sọ ọ́ di ìdàrúdàpọ̀
Wàhálà, bí o bá wá ọkọ̀ Camry rẹ jáde
kí o padà pẹ̀lú dúgìrì iwájú tó ti fọ́.
Wàhálà, bí o bá fi ọkọ̀ rẹ kọjá ibi tí àwọn ọlọ́pàá
ń yẹ ọkọ̀ wò ní òru. Wàhálà, bí ojú ọ̀nà bá dá
Wàhálà, bí o bá jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó wà lẹ́yìn
ọkọ̀. Wàhálà, bí ori rẹ kò bá wá ní fáfá.
Wàhálà, bí o bá wà nítòsí nígbà tí ọlọ́pàá kan bá
yìn ibọn sí ọlọ́pàá mìíràn. Wàhálà, bí wọ́n bá wẹ ẹ̀jẹ̀
ọwọ́ wọn, tí wọ́n sì fi wẹ̀ ọ́. Wàhálà, bí kò bá sí
fídíò tí ó lè fìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀
Wàhálà, bí o kò mọ àwọn aṣòfin olówó ńlá
tí lè gbà ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ ìpọ́njú.
Wàhálà, bí àwọn ọlọ́pàá bá búra pé àwọn kò na ó
Wàhálà, bí wọ́n bá na ọ, tí wọ́n sì ń purọ́.
Wàhálà, bí o bá ti wà nínú ikùn wọn, tí o sì ń
yí káàkiri bí ìfun tí ó ti darú
Nínú ẹ̀wọ̀n. Wàhálà, bí o bá mọ òórùn
ìtọ̀ & ìgbẹ́
Wàhálà fún òkú rẹ tí a kò ní sin
Wàhálà fún ìyá rẹ tí kò ní fẹnukonu ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ tí ó tutù
Wàhálà fún odò tí yóò jẹ́ ọ́.
Wàhálà níhìn-ín, wàhálà níbẹ̀. Wàhálà níbi gbogbo.
Ṣùgbọ́n wàhálà kò sí fún ọlọ́pàá náà
tí ìka-ọwọ́ rẹ̀ tẹ̀ ìbọn bí ẹni tí ìbínú re pọ̀ jọ̀jọ̀.
Wàhálà fún ìjọba tí kò ní ẹ̀tàn mọ́;
wọ́n rò pé àwọn lè pa wá bí ẹṣinṣin.
Wàhálà pé wọn kò mọ̀ pé lílu wọn ti ru
èéfín sókè nítorí pé àgbọn tí ó kún fún ṣẹ́kẹ̀ṣẹ́kẹ̀, a kì í fi ọ̀pá lù ú.
Wàhálà pé wọn kò mọ̀ pé wọ́n
ń sọ wá di dràgọ́ọ̀nì