Bàtà Magazine Logo
african-print-mask

Why Do You Answer in Yoruba

Original Author

Mayowa Oyewale

Translator

Adesiyan Oluwapelumi

Date Published

Why Do You Answer in Yoruba

(Previously published in Frontier Poetry)


III

When I speak to you in English / the way the English do it / thick tongue turning towards / eloquence / Mother / I talk too much / yet a tribe short of myself / crossed beyond the country / learned a language so well / only to start to feel shame

II

In Twi / the word for welcome / is akwaaba / which sounds more like ẹkáàbọ̀ here / same sound & sense / And I start to wonder where both tongues met in history / if they warred internecinal / yet united in a word

I

How gently language leaves the body / is a mystery / I want to be received / in all my fine forgetfulness


Kí lódé tó fi dáhùn ní èdè Yorùbá

III

Tí mo bá bá ọ sọ̀rọ̀ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì/ bí àwọn Òyìnbó ṣe ń ṣe é/ pẹ̀lú ahọ́n tí ó nípọn/ tí ó gbójú nínú ọ̀rọ̀ sísọ/ Ìyá/ Eléjò ni mi/ ṣùgbọ́n mo wà láìní ẹ̀yà kan ti ara mi/ tí ó rẹ kọjá ìlú àbínibí mi/ mo kọ́ èdè yìí dáadáa/ ṣùgbọ́n ìtìjú ní mo ri níbẹ̀

II

Ní èdè Twi/ ọ̀rọ̀ fún káàbọ̀/ jẹ́ akwaaba / èyí dàbí ẹkáàbọ̀ níhìn-ín/ ohùn kan ìtumọ̀ kan/ ó ṣe mí ní kàyéfì íbi tí àwọn èdè méjèèjì ti pàdé ní ìtàn / bóyá wọ́n ti jagun ní àárín ara wọn / ṣùgbọ́n

níṣin wọ́n wà ní ìṣọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ kan

I

Bí èdè ṣe ń fi ara sílẹ̀ pẹ̀lú ìwà pẹ̀lẹ́ / jẹ́ àdììtú / mo fẹ́ kí wọ́n gbà mí / ní gbogbo ìgbà tí mo bá gbàgbé pẹ̀lú ìwà pẹ̀lẹ́

Original Author

MO

Mayowa Oyewale

Translator

AO

Adesiyan Oluwapelumi